Iṣẹ ṣi pọ fun wa lati ṣe o, ẹni lati fara ṣiṣẹ - AbdulRazaq gbawọn kọmiṣanna tuntun lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 5, 2021

Iṣẹ ṣi pọ fun wa lati ṣe o, ẹni lati fara ṣiṣẹ - AbdulRazaq gbawọn kọmiṣanna tuntun lamọran


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lanaa, Ọjọru, Wẹsidee ti gba awọn kọmiṣanaa tuntun mẹta to ṣẹṣẹ bura fun lamọran lati san bantẹ wọn daadaa, ki wọn si ri i daju pe awọn fi ara ṣiṣẹ fun ilu.
 
O ni ki wọn ma ṣe ri ipo naa gẹgẹ bi ipo faaji, bi ko ṣe anfaani lati sin ipinlẹ wọn, paapaa awọn ọmọ ilu wọn tọkantọkan.
 
Hajia Saadatu Modibbo Kawu, kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan; Arabinrin Bọsẹde Ọlaitan, kọmiṣanna fọrọ eto ikansira-ẹni ati Sabbah Yisa Gideon, kọmiṣanna fọrọ eto agbẹ ati idagbasoke agbegbe lawọn mẹtẹẹta ti Gomina AbudulRazaq bura fun.
 
AbdulRazaq sọ pe ọpọ nnkan nijọba ti ṣe lawọn agbegbe wọnyi, ṣugbọn ti wọn ṣi tubọ nilo alabojuto, ki iṣẹ naa le rọrun fun ijọba lati ṣe, nitori pe iṣẹ ṣi pọ nilẹ lati ṣe.
 
IMG_ORG_1628162986261 
Nigba toun naa n sọrọ, akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Mamman Saba Jubril, sọ pe kawọn eeyan naa lo iwa ọmọluabi ti ijọba ri lara wọn, ko to di pe wọn yan wọn, lati fi ṣiṣẹ sin ilu. 
 
Modibbo Kawu, to gba ẹnu awọn kọmiṣanaa meji yoku sọrọ dupẹ lọwọ ijọba fun anfaani ti wọn fun wọn, paapaa igbagbọ ti wọn ni ninu lati yan wọn.
 
Lara awọn to wa nibẹ ni: Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Salihu Yakubu-Danladi; Adajọ agba, Suleiman Kawu; Grand Kadi Ola AbdulKadir; Olori awọn oṣiṣẹ, Arabinrin Modupe Oluwọle Susan; Kọmiṣanna fọrọ eto idajọ, Salman Jawondo; awọn oludamọran pataki fun gomina bi i Sa’adu Salau, ati Bashiru Adigun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI