Ìgbòho kìí ṣe ẹlẹ́wọ̀n, ẹ má ṣe fojú ẹlẹ́wọ̀n wò ó - Agbẹjọ́rò pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 25, 2021

Ìgbòho kìí ṣe ẹlẹ́wọ̀n, ẹ má ṣe fojú ẹlẹ́wọ̀n wò ó - Agbẹjọ́rò pariwo síta


Ọkan lara awọn agbẹjọro olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho, Oluṣẹgun Falọla ti sọ pe ki awọn eeyan ma ṣe ri ọkunrin naa gẹgẹ bi ẹlẹwọn, nitori pe ṣe ni ijọba Benin fi pamọ lati daabo bo ẹmi rẹ ni.
 
Falọla sọ pe o digba ti Aarẹ Buhari ba fipo silẹ, ki Oloye Sunday Igboho to o le pada wọ orilẹ-ede Naijiria, nitori aabo ẹmi rẹ si ni.

Nibi ifọrọwerọ kan Falọla ṣe lo ti sọrọ yii lẹkunrẹrẹ.
 
"Bi wọn ṣe mu Igboho fi han pe ṣe ni wón yan-an jẹ, nitori pe ko ṣe ẹṣẹ ọdaran kankan. Mo n fi asiko yii bẹ gbogbo ọmọ Yoruba ati Naijiria lapapọ, wi pe ki ẹ ma ṣe ri Igboho gẹgẹ bi ẹlẹwọn.
 
"Ẹ ri Igboho gẹgẹ bi ẹni to wa labẹ aabo ijọba Benin. Abẹ ilẹ ni Igboho wa bayii titi digba ti atẹgun alaafia yoo fi fẹ luu.
 
"Ijọba Naijiria ko farahan nile-ẹjọ tabi ki wọn mu awọn ẹri jade lati takoo niwaju ile-ẹjọ. Fun idi eyi, ko ni ẹsun ọdaran kankan ti wọn fi kan an. Nigba ti Igboho ba kuro lẹwọn, o maa beere fun iranlọwọ ibi aabo kaakiri awọn orilẹ-ede, titi di ilẹ Faranse, ti wọn si maa ṣetan lati gba a mọra.
 
"Sibẹ, yoo le pada si Naijiria nigba ti ijọba ti ko fẹran rẹ ba ti kuro nijọba.
 
"Adajọ beere lọwọ Igboho boya o ni ilẹ si Kutọnu, o si loun ni ilẹ si Sẹmẹ. Fun idi eyi, wahala ṣi wa nilẹ fun un. Ibi aabo ti Igboho wa ni Kutọnu ni lati duro si orilẹ-ede naa, ko si maa ṣe okoowo rẹ lọ, ati pe yoo tun lanfaani lati lọ si Germany, yala lati gbe nibẹ ni, tabi lati maa wọle jade bo ba ṣe wu. 
 
"Igboho maa fi Benin ṣe ibugbe tuntun bayii titi digba ti iṣakoso ijọba Buhari maa fi dopin, fun aabo ati alaafia rẹ si ni.
 
"Ṣe lo yẹ ka maa dupẹ lọwọ ijọba Benin wi pe wọn fun un lanfaani lati maa gba itọju. Bẹẹ si ni iyawo rẹ, Rọpo naa n lọ ri i lakooko to ba wu lati gbe ounjẹ lọ fun un loore-koore.
 
"To ba jẹ pe bi wọn ṣe mu Kanu pada si Naijiria ni wọn ṣe mu Igboho ni, a ko le maa sọrọ nipa rẹ lonii. Ilera rẹ yoo ti buru ju ohun ti a n sọ yii lọ. Ẹ wo bi wọn ṣe n ṣe awọn ọmọ ẹyin ẹ ti wọn ko lọjọsi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI