IBD ṣètò ìpàdé alàafíà lààárínHausa àti Yoruba to n ṣiṣẹ ni Dangote nílùú Ìbèṣè - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 20, 2021

IBD ṣètò ìpàdé alàafíà lààárínHausa àti Yoruba to n ṣiṣẹ ni Dangote nílùú Ìbèṣè


Lati le jẹ ki alaafia jọba laarin awọn Yoruba ati Hausa ti wọn ṣiṣẹ nileeṣẹ Dangote, ti ija ti waye ni nnkan bi ọsẹ meloo kan niluu Ibeṣe, nibi ti ọpọ ẹmi ti sofo, ti dukia olowo nla ti bajẹ, Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun, to jẹ Olu-ilẹ Yewa/Awori lapapọ ti pe ipade lati fi yanju awọn aawọ to waye naa ki gbogbo nnkan si maa lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Ipade ọhun to waye yii lọgba Aṣade, Agunloye kẹrin, to wa ni Empire Pavilion, niluu llaro, lọsẹ to kọja yii ni Ọga ọlọpaa Edward Ajogun, to jẹ kọmiṣanna ọlọpa nipinlẹ Ogun, ti rọ awọn olugbe agbegbe naa lati wa ni isọkan, ki wọn si sọra fawọn nnkan to le maa da wahala silẹ laarin wọn, nitori awọn ko le maa woran kawọn kan ma da omi alaafia ru.

Bẹẹ lo tun ke si ljọba lpinlẹ Ogun lati tete wa ojutuu si ọrọ awọn ọlọkada, to maa n fojoojumo da ede aiyede silẹ nipinlẹ Ogun.

Bakan naa lo tun gba awọn ọdọ lamọran lati yẹra fun idajọ ọwọ ara wọn, ki wọn maa tẹle ofin ki wọn to ṣe ohunkohun. 

Ko sai tun sọ fawọn aṣoju lleeṣẹ Dangote, ti wọn wa nibi lpade ọhun lati ri i pe wọn ṣe ojuṣe wọn fawon araalu lbeṣe ati llẹ Yewa lapapo.

Onimọ-ẹrọ, Gbenga Dairo, to ṣoju Gomina Dapọ Abiọdun naa gba awọn Hausa ati Yoruba, to wa niluu lbeṣe lamọran lati yẹra fun lja ẹlẹyamẹya. 

Ṣugbọn Aina Bamgboye, to jẹ olori ọdọ, fi aidunnu ẹ han bawọn ṣoja tawọn lleeṣẹ Dangote pe nigba ti isele naa waye, se pawọn eeyan nipakupa to jẹ kawọn ọmọ faraya lojo naa.

Bẹẹ lo tun mẹnuba bi ileeṣẹ Dangote ko ṣe mu gbogbo lleri ti wọn ṣe fun llu naa ṣẹ.

Ọnarebu Adegoke Awọṣọ, to n ṣoju Ariwa Yewa Akọkọ, nile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, gboriyin fun Alaaji Ibrahim Dende, to ni ootẹli IBD, fun bo ṣe seto ipade alaafia naa, o wa rọ lleeṣẹ Dangote ati awọn aṣoju wọn lati wa ṣalaye biliọnu mẹrin naira, ti wọn na fun ldagbasoke lbeṣe.

Bẹẹ lo ke si awọn agbofinro lati le gbogbo awọn ọmọọta ti ko niṣẹ, ti wọn wa ninu ọja lleeṣẹ Dangote kuro, ki wọn si maa mojuto awọn oko won loorekoore.

Lara awọn ti wọn tun wa nibi lpade naa ni Ọnarebu Haruna Egungbohun, to n ṣoju Yewa North keji, nile igbimo aṣofin nipinle Ogun. 

Bakan naa ni lawọn asoju onimọto, aṣoju awọn ọlọkada atawọn oloye llu lbeṣe pẹlu gbogbo ẹka agbofinro to wa nipinlẹ Ògun lo peju pesẹ sibi lpade alaafia naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI