Ẹsẹ ko gbero ni gbọngan ayẹyẹ to wa nijọba ibilẹ idagbasoke Ojuwoye-Odi-Olowo, Ilupeju nipinlẹ Eko lọjọ Aiku, Sannde ana, nibi ti gbajugbaja pedepede ori redio nni, to tun jẹ akọroyin, Laide Gold ti ṣayẹyẹ ikojade iwe iroyin tuntun.
Iwe iroyin naa, to jẹ magasiini lo pe ni Global Quest Magazine, eyi to fi n gbe aṣa ati iṣe pẹlu awọn agbegbe irin ajo afẹ ilẹ Yoruba larugẹ.
Oduduwa Quest Magazine lorukọ ti iwe iroyin ọhun n jẹ tẹlẹ, ko to pe di pe obinrin naa yi orukọ rẹ pada si Global Quest Magazine, lati le jẹ ki gbogbo agbaye jẹ anfaani igbadun ọlọkan-o-jọkan.
Eto idaraya loriṣiriṣi lo waye nibi ayẹyẹ ikọjade naa, ti awọn eeyan si n royin rẹ titi di akoko ta a ṣakojọpọ iroyin yii tan
Diẹ ree lara fọto bi ayẹyẹ naa ṣe lọ si:
No comments:
Post a Comment