Lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tuside ni gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq tun bu ọwọ lu awọn meji kan fun ipo kọmiṣanna lati le jẹ ki iṣẹ idagbasoke le kẹsẹjari.
Gomina Abdulrazaq lo fi orukọ awọn meji naa ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ṣe agbeyẹwo wọn lai fi akoko ṣofo.
Awọn meji naa ni Oyeyẹmi Florence Ọlasunmbọ lati ijọba ibilẹ Oke-Ero ati Afọlabi Adenikẹ Oṣatimẹhin toun wa lati ijọba ibilẹ Ifẹlodun.
No comments:
Post a Comment