Ọkan lara awọn gtbajugba sẹnetọ lorilẹ-ede yii, Sẹnetọ Nuhu Aliyu ti jade laye lonii.
Sẹnetọ Aliyu ti figba kan ri ṣoju ẹkun Ariwa ipinlẹ Niger. Ilu Kaduna la gbọ pe o ku si lonii, Ọjọru, Wẹsidee, lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo kọluu.
Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, ijọba ipinlẹ Niger sọ pe ọkunrin to lakikanju, ẹni to ja fitafita fun ipinlẹ Kaduna ni nigba aye ẹ.
Ninu atẹjade ti Alaaji Ahmed Ibrahim Matane, ẹni to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ naa fi sita lo ti sọ pe adanu nla niku Sẹnetọ Aliyu jẹ fawọn.
No comments:
Post a Comment