Ẹgbẹ akẹkọọ lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn National Association of Nigerian Students (NANS), ẹka tipinlẹ Kwara ti fi awọọdu manigbagbe ta oludamọran pataki lori iroyin ayelujara, fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ naa, Ọgbẹni Ọlayinka Michael Fafoluyi lọrẹ.
Nibi eto ayẹyẹ ti ẹgbẹ akẹkọọ naa ṣe lori ọrọ to ni i ṣe pẹlu eto aabo loni ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tuside ni Ọlayinka Fafoluyi ti gba awọọdu lati fi mọ riri ipa to n ko lori eto aabo, paapaa nipa awọn akẹkọọ.
Gbọngan keji to wa ninu ọgba ile ẹkọ Kwara State College of Education, ilu Ilọrin ni eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni SECURITY, SUMMIT AND CAMPUS ENLIGHTENMENT ti waye.
Awọn akẹkọọ naa lawọn ipa ti ọkùnrin naa n ko lori ọrọ eto aabo, paapaa laaarin awọn akẹkọọ ko kere rara, tawọn si gbọdọ wa nnkan to le ṣe koriya fun un.
Nigba toun naa n sọrọ, Fafoluyi sọ pe oun ko le ṣai ma ṣe ojuṣe oun gẹgẹ bi ẹni to sunmọ awọn akẹkọọ daadaa, ati pe ipa ti wọn n ko ninu idagbasoke orilẹ ede yii, paapaa nipinlẹ naa ko kere.
O wa fi ẹmi imoore rẹ han si wọn.
Diẹ ree lara bi awọọdu naa ṣe lọ si:
No comments:
Post a Comment