Ẹgbẹ DACA lọ bawọn kẹdun iku Baba Gomina Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 8, 2021

Ẹgbẹ DACA lọ bawọn kẹdun iku Baba Gomina Abiọdun


Ẹgbẹ kan to n fẹ ki Dapọ Abiọdun tẹsiwaju ninu erongba ẹ iyẹn Dapọ Abiọdun Continuity Agenda (DACA) ti lọ bawọn kẹdun iku Baba Gomina ipinlẹ Ogun, Alagba Emmanuel Abiọdun.

Lọjọ Furaidee, to kọja yii lawọn eeyan ọhun lọ s Ipẹru, nibi ti wọn ti darapọ mọ awọn eeyan to wa nibẹ, ti wọn fọwọ si iwe fun ti ibanikẹdun ọhun, awọn aṣoju wọn to wa nibẹ ni Ọnarebu Adedayọ Ọkanlawọn Akintoye, Ọnarebu Muiz Ọladehinde Omitogun, Ọnarebu Olujimi Adekunle Desmond ati Ọnarebu Saheed Balogun.

Ninu iwe ọhun ni wọn ti ṣapejuwe Oloogbe naa gẹgẹ bi Baba daadaa to ti kopa to jọju paapaa nidii iṣẹ tiṣa, to si tipa iṣẹ ọhun tun igbe aye ọpọ awọn eeyan ṣe.

Wọn ni gbogbo awọn lawọn yoo ṣe afẹẹri ẹ, bakan naa ni wọn tun sọ pe Baba yii jẹ olufọkasin nigba aye to si tun tọpọsẹ awọn ọmọ ẹ naa sinu igbagbọ, wọn wa gbadura pe ki Ọlọrun fọrunkẹ, ki o si tu awọn mọlẹbi ẹ, paapaa Gomina Dapọ Abiọdun ninu.

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI