Kayeefi nla gba a lọrọ awọn mọlẹbi kan ti wọn ko din ni mẹrinlọgbọn ti wọn jẹ ounjẹ majele, to si ran awọn mẹrinlelogun ninu wọn lọ sọrun aremabọ, ṣugbọn ti meji yooku wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Kọmiṣanna fọrọ eto ilera nipinlẹ Sokoto, Ali Inname lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii wi pe awọn mẹrinlelogun naa ti ku lai ni anfaani lati doola ẹmi wọn.
Inname sọ pe ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii niṣẹlẹ ọhun waye labule kan ti wọn n pe ni Danzanke, ni Bargaja, ijọba ibilẹ Isa.
AWIKONKO gbọ pe ounjẹ ti wọn fi ajilẹ kan ti wọn n pe ni “Gishirin Lalle” lede Hausa gbin lo ṣeku pa gbogbo wọn.
Wọn ni awọn meji pere ti wọn tọ ounjẹ naa wo, ti ki i ṣe pe wọn jẹ ẹ ni wọn wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, ti igbagbọ si wa pe wọn ko ni i ku.
Loju ẹsẹ ni wọn ti ko oku awọn eeyan naa wọ mọṣuari.
Inname wa a gba awọn eeyan lamọran lati lo ohun to ṣẹlẹ naa gẹgẹ bi arikọgbọn, ki wọn si yago fun oniruuru ounjẹ to le ṣee ṣe ko ṣeku pa eeyan, ko to di pe wọn jẹ ẹ.
No comments:
Post a Comment