Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ba Ẹmir tilu Kaiama, Alaaji Muazu Shehu Omar, Kiyaru kẹrin yọ lori ayẹyẹ igbade ọdun kọkanla to n waye lonii, ọjọ satide, Abameta.
Ninu atẹjade ikini ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye fi ranṣẹ s'AWIKONKO laipẹ yii lo ti ṣapejuwe Emir naa gẹgẹ bi ẹni to n gbe alaafia ga laaarin ilu, to si n wa gbogbo ọna lati mu idagbasoke ba agbegbe rẹ.
Gomina AbdulRazaq gbadura alaafia ati ẹmi gigun fun Emir naa, to si ni igba rẹ n tu awọn eeyan rẹ lara, nipa eto aabo ati iṣọkan.
No comments:
Post a Comment