Afaimọ ni ko ma jẹ pe idajọ iku ni wọnn yoo pada da fun ẹnikan ti wọn lo pa ọmọ oojọ nipakupa, to si tun ju oku ọmọ naa sori fẹnsi ile akọku kan nipinlẹ Niger.
Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii ni ko ti i sẹni to le sọ pato nipa ẹni to ṣiṣẹ buruku naa, ṣugbọn ti a gbọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.
AWIKONKO gbọ pe ori fẹnsi ile akọku kan to wa lagbegbe Dutses Kura, iyẹn agbegbe kan tawọn Hausa tẹdo si nipinlẹ naa ni wọn ti ri oku ọmọ yii, lori irin ti wọn fi n daabo bo ile, iyẹn Barbed Wire.
Ẹjẹ oku ọmọ naa ti wọn wọn lo kan silẹ lo jẹ kawọn to n kọja lọ tete mọ, ti wọn si ranṣẹ pe olori agbegbe yii, Ahmad Tukura.
Tukura nigba to n sọrọ sọ pe ẹdun ọkan nla lo jẹ foun atawọn eeyan, nitori to sọ pe ṣe lo yẹ ki ẹni to bi ọmọ naa gbe e sẹgbẹ titi fawọn eeyan lati gbe e, ki wọn si tọju ẹ, tabi pe ki wọn gbe e lọ sile awọn ọmọ alailobi.
No comments:
Post a Comment