Àwọn tọ́ọ̀gì gbé ìbọn sí oníròyìn lórí láti ka ìròyìn ní tipátipá lórí tẹlifíṣàn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 31, 2021

Àwọn tọ́ọ̀gì gbé ìbọn sí oníròyìn lórí láti ka ìròyìn ní tipátipá lórí tẹlifíṣàn


Awọn tọọgi agbebọn ti Taliban lorilẹ-ede Afghanistan ni wọn ti gbe ibọn si gbajugbaja oniroyin kan lori lati le ka iroyin ti wọn n fẹ ni tipatiapa.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni ṣe lawọn tọọgi Taliban naa yawọ ileeṣẹ amohunmaworan kan pẹlu ibọn, ti wọn si ni kawọn to n ṣeto lọwọ bẹrẹ sii gbe oṣuba kare fun ijọba Taliban to n ṣakoso lọwọ.
 
Ko din ni awọn tọọgi agbebọn mẹjọ ti wọn koju ibọn sori oniroyin naa, wi pe awọn fẹ ko gbe oriyin fun ijọba to wa nita.

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI