Gbogbo awọn obinrin ipinlẹ Kwara jakejado ni wọn ti sọ pe awọn ti ṣetan bayii lati ṣatilẹyin to ba yẹ fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq pẹlu bo ṣe ka wọn kun ninu ijọba rẹ, ati awọn idagbasoke ọlọka-o-jọkan to n ṣe lọwọlọwọ.
Ojọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii lawọn obinrin ọhun sọ pe inu awọn dun, ọkan awọn si balẹ lori iṣakoso Gomina AbdulRazaq, nitori pe awọn ohun to n ṣe ko ti i ṣẹlẹ ri nin u itan ijọba ipinlẹ Kwara.
Wọn ni akọkọ ree ti ijọba yoo maa ka awọn obinrin kun ninu iṣakoso wọn, ati pe wọn ko jẹ ki ọkunrin pọ ju obinrin lọ ninu iṣakoso ọhun, bẹẹ ni wọn sọ pe eyi ti gbe pupọ awọn obinrin dide kurọ ninu iṣẹ ati oṣi bọ sinu igbadun.
Gbagede papa iṣere ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State Stadium Complex, ni agbarijọ awọn obinrin ninu oṣelu, okoowo, amuludun ati ere idaraya ti peju-pesẹ lati sọ pe "AbdulRaza, maa ba iṣẹ rẹ lọ..Iṣẹ rẹ maa n tẹ wa lọrun..."
Oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ irolagbara awọn obinrin, Hajia Bolanle Ismail, lo ṣagbatẹru eto naa, ti ogunlọgọ awọn obinrin ni ẹka o jẹka ti pesẹ sibẹ, nibi ti wọn tun ti lo anfaani yii lati dupẹ lọwọ ijọba mẹkunnu wọn.
No comments:
Post a Comment