Awọn meje padanu ẹmi wọn nibi ija Hausa ati Yoruba to waye l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 5, 2021

Awọn meje padanu ẹmi wọn nibi ija Hausa ati Yoruba to waye l'Ogun


Awọn ti ko din ni meje la gbọ pe wọn ti sọda sọrun alakeji nibi ija ẹlẹyamẹya to waye laaarin ẹya Hausa ati Fulani, eyi to ṣẹlẹ lagbegbe Ibeṣe, ijọba ibilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun.
 
Bo tilẹ jẹ pe awọn meji nileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn le ṣakọsilẹ rẹ lanaa, Ọjọru, Wẹsidee, ṣugbọn ti iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe meje lawọn to dagbere faye, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
 
Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọkada atawọn oniwe tikẹẹti ni wọn n ba ara wọn fa wahala, ko to di pe ọrọ naa pada yiwọ mọ wọn lọwọ, to fi di pe ija naa di ẹlẹyamẹya.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe lawọn to n ja tikẹẹti sọ owo tikẹẹti di ẹgbẹrin naira, eyi to le ni igba naira si owo ti wọn n san tẹlẹ. Ẹgbẹta naira ni wọn san tẹlẹ.
 
Bi wọn ṣe fi owo kun wo tikẹẹti yii lo bi awọn ọlọkada naa ninu, ti wọn fi sọ pe awọn ko le san owo naa, nitori pe o ti pọ ju agbara wọn lọ.
 
Ibi ti wọn ti n sọ ọrọ yii, lẹyin tawọn ọlọkada ṣe ipade, ni wọn sọ pe awọn ọlọkada kan tawọn jẹ Hausa ti sọ pe iye ti wọn gbe owo naa si lawọn yoo san, ti wọn si ni ninu wọn ti ja tikẹẹti yii ni ẹgbẹrin naira.
 
Eyi ni wọn lo bi awọn ọlọkada ti wọn jẹ Yoruba ninu, to fi di pe wọn lọ koju awọn ọlọkada Hausa naa, ti ọrọ si di iṣu ata yannyann.
 
AWIKONKO gbọ pe ọpọ dukia lo ṣofo danu nibi ikọlu naa lọjọ Tusidee ati Wẹsidee ana, koda, ti wọn sọ pe wọn tun dana sun awọn tirela Dangote meloo kan.
 
Bi wahala naa ṣe n lọ lọwọ la gbọ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti ko awọn ọlọpaa rẹ lẹyin lati lọ sibẹ, ko le pana wahala ọhun.
 
Titi dasiko ta a pari iroyin yii nijọba ipinlẹ Ogun ko ti i sọ ohunkohun lee lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI