Awọn mọlẹbi gbajugbaja agba oṣere tiata to jade laye lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, Rachel Oniga ti sọ pe ki i ṣe arun korona lo pa eeyan awọn gẹgẹ bawọn kan ṣe n gbe e kaakiri.
Wọn ni o ti ṣe diẹ ti aisan ọkan ti n ba Rachel finra, to si n gba itọju.
Ninu ọrọ ti ọkan lara awọn aburo Rachel Oniga, Diakoni Toyin Oduṣọtẹ gbe sita lorukọ mọlẹbi lo ti sọ pe awọn to gbe iroyin naa jade ko mọ ohun to ṣẹlẹ, lo jẹ ki wọn maa wa awawi.
Bakan naa lo tun sọ pe awọn yoo sọ bi eto isinku Rachel yoo ṣe lọ sita laipẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Pẹlu ibanujẹ ọkan la n sọ fun un yin nipa ọrọ iku ẹgbọn wa, mama wa ati mama-mama wa, Oloye Rachel Tabuno Oniga.
"Ọsibitu l'Ekoo lo ku si lẹni ọdun mẹrinlelogoji, lọjọ Furaidee, ọgbọn ọjọ, oṣu keje, ọdun 2021, ni nnkan bi aago mẹwaa alẹ.
"Lati le fidi awọn oriṣiriṣi iroyin to ti n lọ kaakiri mulẹ wi pe arun Konora lo pa a, la fi n kọ eyi jade lati fi to gbogbo eeyan leti wi pe aisan ọkan lo ṣeku pa a, aisan naa to jẹ pe ko pẹ rara to fi ba a finra, ko to di pe o jade laye."
No comments:
Post a Comment