Ẹgbẹ oṣẹlu All Progressives Congress, APC lorilẹ-ede yii ti gbe igbimọ ti yoo ri sọrọ aawọ to dide lẹyin ipade gbogboogbo wọọdu ẹgbẹ naa to waye laipẹ yii dide.
Alaga fidihẹ to n ri sọrọ ipade gbogboogbo ẹgbẹ ọhun, iyẹn Caretaker/Extraordinary Convention Planning Committee (CECPC), Gomina Mai Mala Buni l'Ojọru, Wẹsidee ana lo gbe igbimọ naa dide lati tete bẹ gbogbo awọn tọrọ kan lati wa ni iṣọkan.
Nigba to n bura fawọn igbimọ naa kaakiri Naijiria nilu Abuja, akọwe CECPC, Sẹnetọ John James Akpanudoedehe gbawọn lamọran lati ma ṣe ṣe ojusaaju ẹnikẹni ninu yiyanju aawọ ọhun, bi ko ṣe pe ki wọn ṣe ohun to tọ, ki alaafia le tubọ jọba.
No comments:
Post a Comment