Wọ́n ti ju Abdulsalam sẹ́wọn ọdún kan gbáko n'Ílọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 31, 2021

Wọ́n ti ju Abdulsalam sẹ́wọn ọdún kan gbáko n'Ílọrin


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara, eyi to fikalẹ siluu Ilọrin ti ju Abdulsalam Oyeyẹmi sẹwọn ọdun kan gbako, pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan-an.

AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Abdulsalam, ọmọ ọdun mẹtalelogun naa n pe ara rẹ ni ọkan lara awọn ṣọja ilẹ Amẹrika, to si fi n gba owo lọwọ awọn alaimọkan kaakiri.

Onidajọ Mahmood Abdulgafar to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe awọn ẹri toun ri gba fi han pe wọn ko purọ mọ ọn.

Ileeṣẹ EFCC, ẹka tiluu Ilọrin ni wọn foju Abdulsalam ba ile-ẹjọ naa l'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja.

Ẹsun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu jibiti ori ayelujara ni wọn fi kan Absulsalam, toun naa si ni loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Ọgba ẹwọn Manadala to wa niluu Ilọrin ni Onidajọ Mahmood Abdulgafar sọ pe ki Abdulsalam to ṣe ẹwọn ọdun kan naa, bẹẹ lo paṣẹ pe iPhone ti wọn gba lọwọ ẹ ati iwe sọwedowo ẹgbẹrun lọna igba naira ni ki ijọba gbesẹ le.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI