Wọn layẹyẹ Ojude Ọba ko ni i waye lọdun yii o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 5, 2021

Wọn layẹyẹ Ojude Ọba ko ni i waye lọdun yii o


Bi iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe o tun ti di ọdun keji bayii ti gbajugbaja ayẹyẹ aṣa ati iṣe ilẹ Ijẹbu lapapọ, eyi ti wọn pe ni Ojude Ọba, to maa n waye lọdọọdun nilu Ijẹbu Ode ko tun ni waye lọdun yii mọ.
 
Gbogbo ọjọ kẹta si ọdun Ileya tawọn Musulumi maa n ṣe kaakiri agbaye ni ayẹyẹ naa maa n waye niluu Ijẹbu Ode, ipinlẹ Ogun.
 
Bẹ o ba gbagbe, ayẹyẹ naa ko waye lọdun to kọja, iyẹn ọdun 2020. Ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe ti ajakalẹ arun Korona, COVID-19 to n ba gbogbo agbaye finra lọwọ, eyi to jẹ ki wọn fofin de ipejọpọ elero rẹpẹtẹ.
 
Ẹnikan to sunmọ aafin Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, ẹni ta a forukọ bo laṣiri lo tu aṣiri naa sita.
 
Bo tilẹ jẹ pe ẹni naa sọ pe oun ko ti i le sọ kulẹkulẹ idi ti ayẹyẹ naa ko fi ni i waye lọdun, ṣugbọn o jẹ ko ye wa pe ko ti i si idaniloju wi pe ayẹyẹ Ojude Ọba ọhun yoo waye.
 
Bakan naa lawọn alakoso atawọn to n ṣagbatẹru eto yii lọdọọdun ko ti i sọrọ sita nipa boya wọn yoo ṣe e tabi ko ni i waye, ṣugbọn ti idaniloju ti n wa wi pe ayẹyẹ naa ko ni i waye lọdun 2021 ti a wa yii.
 
A gbọ pe bi ayẹyẹ naa yoo ba waye lọdun yii, ọjọ kẹtalelogun oṣu keje ti a wa ninu rẹ yii ni wọn yoo ṣe, ṣugbọn ti ko ti i si imọlara wi pe wọn yoo ṣe e.
 
Ọdun 2019 ni ayẹyẹ naa ti waye gbẹyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI