Iya agba kan, Arabinrin Dora Animan ati ọmọ rẹ, Gift Kenneth, to fi mọ ololufẹ ọmọ rẹ, Spice Chimzi Dandy Igwe ni ile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Asaba, ipinlẹ Delta ti ju sẹwọn ọdun marun-un-marun-un ati ọdun mẹta gbako lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn.
Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii ni Onidajo F. A. Olubanjọ gbe idajọ naa kalẹ fun awọn mẹtẹẹta lori ẹsun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu jibiti.
Dora Animam ati ọmọ rẹ, Gift Kenneth ni wọn ju sẹwọn ọdun marun-un-marun-un, nigba ti wọn ju Spice Chimzi Dandy Igwe sẹwọn ọdun mẹta pere.
Awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC to n gbogun ti iwa jibiti ni Naijiria lo foju wọn ba ile ẹjọ
Obinrin, ọmọ ilẹ Amẹrika kan ti wọn pe ni Lucinda Ann Garnes Henrichson la gbọ pe wọn lu ni jibiti obitibiti owo to to $902,935 //laaarin ọdun 2018 si 2019
Wọn ni orukọ Raymond Carl Eric ni Gift fi lu Lucinda ni jibiti owo naa ko to di pe aṣiri pada tu sita.
Wọn ni orukọ Raymond Carl Eric ni Gift fi lu Lucinda ni jibiti owo naa ko to di pe aṣiri pada tu sita.
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, Onidajọ Olubanjọ sọ pe gbogbo ẹru ti wọn gba lọwọ wọn ni ijọba ti gbẹsẹ le patapata, ki wọn si ta a lati da owo naa pada fun ẹni ti wọn gba a lọwọ ẹ.
Diẹ ree lara awọn fọto nnkan ti wọn gba lọwọ wọn:
No comments:
Post a Comment