Wàhálà APC: Ilé-ẹjọ́ lé igun Lai Mohammed danù l'ọ́fíìsì tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 31, 2021

Wàhálà APC: Ilé-ẹjọ́ lé igun Lai Mohammed danù l'ọ́fíìsì tuntun


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara ti le igun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to jẹ ti minisita fọrọ eto iroyin ati aṣa lorilẹ-ede yii, Alaaji Lai Mohammed danu ni ọfiisi tuntun ti wọn ṣẹṣẹ lọ ọ gba.
 
Ninu iwe idajọ naa to waye niluu Ilọrin lanaa, ọjọ Ẹti, Furaidee, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti sọ pe ki wọn ti ọfiisi naa pa, ati pe wọn ko gbọdọ ṣe ohunkohun to jẹ mọ ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC nibẹ mọ.

Igun ẹgbẹ naa la gbọ pe Bashir Ọmọlaja Bọlarinwa jẹ alaga rẹ.
 
Agbegbe GRA, to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa la gbọ pe wọn lọ ṣi ọfiisi tuntun yi si lẹyin ti wahala dide ninu ẹgbẹ APC.

Ẹnikan ti wọn pe ni Yahya Madawaki, ẹni to ni ile ti wọn sọ di ọfiisi yii la gbọ pe o gbe igun ẹgbẹ naa lọ sile-ẹjọ lati le wọn danu, nitori pe oun fẹẹ lo ile oun.

Iwe ipẹjọ naa ni nọmba rẹ jẹ KWS/234/2021, eyi ti Abidemi Adisa pe lorukọ mọlẹbi.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI