Ta ló n bẹ̀ru Aṣíwájá Tinubu? Ẹ lọ ṣọra yin o, digbí lara rẹ̀ wa - Rahman - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 31, 2021

Ta ló n bẹ̀ru Aṣíwájá Tinubu? Ẹ lọ ṣọra yin o, digbí lara rẹ̀ wa - Rahman


Laipẹ yii ni iroyin kan jade sita wi pe ara Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lorilẹ-ede yii, Oloye Bọla Ahmẹd Tinubu ko ya gidi, ati pe ọsibitu nibi to ti n gba itọju lọwọ lo wa.

Iroyin naa sọ ọ debi wi pe ṣe ni wọn fi irinṣẹ igbalode kan gbe ẹmi Aṣiwaju Tinubu duro, ko ma ba a jade laye.

Ṣugbọn nigba to n tako iroyin naa, agbẹnusọ Tinubu lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Tunde Rahman sọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni, ati pe awọn ọta Tinubu lo wa nidi iroyin buruku naa.

Rahman ninu atẹjade to gbe jade lonii, ọjọ Satide, Abamẹta lo ti sọ pe:

"Ko si nnkan to ṣe Ọlajulọ Aṣiwaju Bọla Tinubu. Digbi ni ara rẹ wa. Ko si ni ọsibitu kankan. Ko ni ipenina ilera to nilo ki wọn daa duro si ọsibitu.

"Bẹẹni, ko si lorilẹ-ede lọwọlọwọ bayii. O maa de laipẹ. Nigbakugba to ba ti rin irin ajo kuro lorilẹ-ede yii, ohun to kan kawọn eeyan maa gbe kaakiri ni pe ara rẹ ko ya, wọn daa duro sọsibitu tabi pe o ti ku.

"O jẹ nnkan itiju wi pe awọn to maa n wa nidi iroyin ẹlẹjẹ yii maa n pada ri i pe lẹyin ti wọn ba ti gbe iroyin yii jade, ni wọn maa n ri i pe irọ lawọn n pa.

"Awọn wo gan-an lo n bẹru Aṣiwaju Tinubu? Ki awọn ti wọn n ro ibi ro Aṣiwaju Tinubu tabi yi wọn n ro iku ro o lọ ṣọra. Ki wọn mọ pe ọrọ iku ati aaye wa lọwọ Ọlọrun Alagbara."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI