Laipẹ yii ni ọkan lara awọn to sunmọ Oloye Sunday Adeyẹmọ Igboho daadaa sọrọ jade, to si ni ọkunrin naa ti ran oun si gbogbo awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye wi pe inu alaafia ati ifọkanbalẹ loun wa lahamọ ti wọn gbe oun pamọ si.
Gẹgẹ bi fọnran ti BBC Yoruba gbe jade sori ikanni wọn laipẹ yii, nibi ti ọkunrin naa to pe ara rẹ ni Alaaji Idris Ọladẹjọ, ẹni to jẹ ọkan lara awọn aafa Igboho sọrọ yii.
O ni "Baṣọrun Sunday Igboho, ni aarọ yii ti mo ri i, mo fi Mẹka ati Mẹdina ti mo lọ bura, mo fi Ọlọrun to ni ẹmi mi bura. Mo fi sanmọ ati ilẹ bura. Oloye Akọni ilẹ Oodua Sunday Igboho, o wa daadaa, ko si nnkan to ṣe e.
"O wa layọ ati alaafia, ko banujẹ. Walahi ko banujẹ. Baṣọrun Sunday Igboho ko banujẹ rara, o wa ni alaafia. O ni ki n sọ fun gbogbo ọmọ Oodua pe aburu kankan ko ni ṣẹlẹ soun.
"O ni Ọlọrun ko ni fi oun Sunday Igboho pa ẹnikankan lẹkun lagbara Ọlọrun. Ọlọrun ko ni si ni fi ẹnikankan wa naa pa Sunday Igboho lẹkun. Ninu kọọtu ti a wa yii, Sunday n lọ, o n bọ lai si wahala kankan, nitori pe ijọba Benin ti ri ododo wi pe wọn kan fẹẹ da ẹmi Sunday Igboho legbodo ni.
"Wọn ti ri i pe Sunday Igboho ki i ṣe ọdaran, ọmọluabi to n ja fun ẹtọ ọmọniyan ni. Wọn ni ṣe iwadii finni-finni, ko da bi Naijiria to jẹ pe wọn kan maa ṣe idajọ bo ṣe wu wọn, to jẹ pe wọn a kan pa eeyan bo ṣe wu wọn.
"Gbogbo bi wọn ṣe paayan sile Sunday Igboho ni wọn ti ri aridaju ẹ, wọn ti ṣe iwadii wọn kikun, bẹẹ ni wọn ki i ṣe idajọ bo ṣe wu wọn. O ni ki n ba oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan patapata, walahi, mo fi titobi Ọlọrun to ni ẹmi mi bura. O wa layọ ati alaafia, ṣugbọn ko ti i si anfaani lati fọrọwalẹnu wo.
"Ko ti i si anafaani lati ba gbogbo aye sọrọ, ko ti i si anfaani lati ba gbogbo ẹyin ololufẹ rẹ sọrọ, ṣugbọn o sọ pe ki n ki i yin daadaa, ẹ si ku aduro ti oun kaakiri agbaye."
No comments:
Post a Comment