Saheed táwọn ọlọ́pàá yìnbọn fún l'Ọ́ṣun ti jáde láyé o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 31, 2021

Saheed táwọn ọlọ́pàá yìnbọn fún l'Ọ́ṣun ti jáde láyé o


Awọn alaṣẹ ọsibitu Osun State University Of Technology to wa niluu Oṣogbo ti fidi rẹ mulẹ wi pe Saheed Ọlabomi, ẹni ọgbọn ọdun ti awọn ọlọpaa yinbọn fun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ti jade laye.
 
Nnkan bi aago mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹdogun la gbọ pe Saheed, ti wọn ni ko niṣẹ meji ju iṣẹ ọkada lọ jade laye lẹyin ọpọlọpọ itọju, ti ko si ri oluranlọwọ.

Wọn ni wọn ti gbe oku rẹ lọ si mọṣuari latigba to ẹlẹmi ti gba a.
 
Intensive Care Unit ọsibitu naa la gbọ pe Saheed wa nibi ti wọn ti n doola ẹmi rẹ latigba ti ibọn ti ba a, ti a si gbọ pe latigba naa lawọn mọlẹbi rẹ ti n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ọṣun fun iranlọwọ, ṣugbọn ti wọn ko da wọn lohun, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
 
Aṣita ibọn ti ọlọpaa kan yin la gbọ pe o ba Saheed, to si ran an lọ sọrun apapandodo.
 
Alukoro ọsibitu naa, Ọgbẹni Ayọdele Adeyẹmọ, nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe Saheed jade laye lẹyin iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fun un.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI