Lanaa, ọjọ Aiku, Sannde ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde wọ ṣọọṣi Living Spring Chapel International to jẹ ti agba ojiṣẹ Ọlọrun nni, Pasitọ Fẹmi Emmanuel, eyi to wa niluu Ibadan, ipinlẹ naa.
Nibi ayẹyẹ idupẹ ọjọ ibi agba pasitọ naa ti wọn ninu ṣọọṣi rẹ, eyi ti Ṣeyi Makinde ti jẹ alajo pataki, lo ti gba ẹbun adura lati ẹnu olori ati oludasilẹ ijọ ọhun.
Yatọ si Ṣeyi Makinde, iyawo rẹ, Arabinrin Tamunominini Makinde ati ọmọ wọn ọkunrin ni wọn jọ kọwọ rin lọ ba Pasitọ Fẹmi Emmanuel ṣe isin idupẹ naa.
Gomina Ṣeyi Makinde funra rẹ naa wa lo anfaani nla yii lati gba gbogbo eeyan, paapaa awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lamọran, lati kun fun adura, ki alaafia le tubọ maa jọba nipinlẹ Ọyọ.
No comments:
Post a Comment