Owó tí à ń gbà ní ṣọ́ọ̀ṣì Winners kò pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà - pásítọ̀ tí wọ́n dá dúró pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 25, 2021

Owó tí à ń gbà ní ṣọ́ọ̀ṣì Winners kò pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà - pásítọ̀ tí wọ́n dá dúró pariwo síta


Ọkan lara awọn pasitọ ogoji ti wọn da duro ni ṣọọṣi Living Faith, iyẹn Winners Chapel to jẹ ti Pasitọ David Oyedepo ti sọ pe aaontko gba owo to wọ ẹgbẹrun lọna ogoji naira, depodepo ọgọrin ẹgbẹrun ti wọn sọ.

Pasitọ naa to fi orukọ bo ara rẹ laṣiri sọ pe iye owo to pọ ju tawọn n gba gẹgẹ bi owo oṣu ni ẹgbẹrun mẹtalelaadọta (₦53,000) naira.

O ni ki i ṣe gbogbo owo naa lo n tẹ wọn lọwọ bi oṣu ba ti pari, bi ko ṣe pe ẹgbẹrun mejidinlogoji (₦38,000) naira lowo ti wọn n san wọle fun.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Pasitọ Peter Godwin, to jẹ ọkan lara awọn Pasitọ ti wọn da duro ninu ṣọọṣi Winners, tu aṣiri naa sita fun gbogbo agbaye, to si ni wọn ko kilọ fun wọn tẹlẹ ki awọn alaṣẹ to gbe igbesẹ yii.

Lẹyin rẹ ni olidasilẹ wọn, Biṣọọbu David Oyedepo sọrọ sita nipa idi to fi fọwọ si idaduro gbogbo wọn lojiji wi pe wọn ko so eso rere ni.

Ẹni kan naa to tun sunmọ ijọ yii daadaa, ninu ọrọ to gbe jade sori ikanni ayelujara lẹyinti Biṣọọbu Oyedepo ti sọrọ jade sọ pe owo tawọn eeyan naa n gba pọ rẹpẹtẹ, ti wọn ko si ṣiṣẹ wọn bo ti tọ, ati bo ti yẹ.

Ọkunrin naa sọ pe bi wọn ṣe da awọn Pasitọ naa duro dara, nitori pe apapọ owo to pọ ju, ti pasitọ kan n gba ni ẹgbẹrun mẹtalelaadọta naira naa loṣu, iyẹn awọn to ba niwe ẹri BSc, ti si jẹ pe ko si ẹni to n gba gbogbo naa pe loṣu.

"Oyedepo ati awọn Pasitọ agba ti mọ pe awọn yoo da wa duro ko to di pe wọn gba wa siṣẹ rara. Idi ree ti wọn fi gba wa wi pe ki wọn ṣi maa wo wa, iyẹn 'employment on probation'.

"Ẹni kan lọ sori ayelujara lati kọ irọ oriṣiriṣi sibẹ lati kin ijọ naa lẹyin wi pe gbogbo awọn pasitọ ti wọn da duro n gba owo oṣu ọgọrin ẹgbẹrun naira ati ẹgbẹrun lọna ogoje naira gẹgẹ bi owo ile.

"Diẹ ni nnkan ti emi fẹẹ sọ lee lori, ko si pasitọ ti wọn gba to n gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira ninu ṣọọṣi naa. Owo to pọ ju ti ẹni to ni iwe ẹri BSc n gba ni ẹgbẹrun mẹtalelaadọta naira. Owo yii si ree, ki i ṣe gbogbo rẹ lo n tẹ wọn lọwọ ni ipari oṣu.

"Ẹgbẹrun mejidinlogoji ni wọn n gba ni ipari oṣu; ẹgbẹrun mẹfa n lọ sinu apo owo ifẹyinti, ẹgbẹrun mẹsan n lọ sinu apo owo ile.

"O ya wa lẹnu, o si tun jẹ ohun to panilẹrin wi pe awọn pasitọ yii ti a n bọwọ fun le ko owo ti wọn yọ sapo wọn, ti wọn ko si ko o sibi to yẹ. Ẹyin ti wọn da wa duro ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ si i san owo naa sinu apo owo ifẹyinti wa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI