Bi wọn ba n sọ pe taa ni ọpẹ tọ si lẹnu lakooko yii, awọn mẹta kan ti a gbọ pe ori ṣẹṣẹ ko yọ lọwọ iku ojiji lagbegbe Majeroku to wa lopopona Gbọgan siluu Ibadan, iyẹn nipinlẹ Ọṣun ni.
Aarọ oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee la gbọ pe awọn mẹtẹẹta kagbako ijamba ọkọ naa, ṣugbọn to jẹ pe Ọlọrun ko wọn yọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni tirela nla meji ọtọọtọ, iyẹn tirela Mack to ni nọmba idanimọ KTU774XW ati tirela DAF toun ni nọmba idanimọ LSD314XX, ni wọn gba ara wọn ni nnkan bi aago mẹta ku iṣẹju mẹẹdogun oru.
Awọn mẹta naa la gbọ pe wọn wa ninu tirela mejeeji yii, ti nnkan ko si ṣe wọn.
Ere asapajude la gọ pe o fa a, ti awọn mejeeji fi doju kọ ara wọn.
Nnkan bi agogo mẹjọ aabọ aarọ yii ni wọn ṣẹṣẹ fi iṣẹlẹ naa ti ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ lorilẹ-ede yii, FRSC leti, ti wọn fi sare lọ sibẹ, iyẹn gẹgẹ bi agbẹnusọ wọn, Agnes Ogungbemi ṣe sọ.
No comments:
Post a Comment