Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò OGSIEC ni kí wọ́n máa múra ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ - Ọ̀gínní pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 27, 2021

Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò OGSIEC ni kí wọ́n máa múra ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ - Ọ̀gínní pariwo síta


Ọgbẹni Sunday Ọlapọsi Ọginni, alaga fẹgbẹ oṣelu New Nigerian People Party, NNPP, nipinlẹ Ogun, ti ṣeleri pe, pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, oun ṣetan lati ran awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo  ipinlẹ Ogun, OGSIEC, lẹwọn, lori ipa magomago ti wọn ko ninu eto idibo ijọba ibilẹ to waye lọjọ Satide, to kọja yii.

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi ipade oniroyin to waye lonii,  bẹẹ lo tun sọ pe awọn ti gbaradi lati lọ sile-ẹjọ lori esi idibo to waye ọhun, pẹlu igbagbọ pe awọn ti yoo gbọ ẹjọ naa ko ni figba kan bọ kan ninu.

Ọginni sọ pe gbogbo awọn araalu gan lo mọ pe magomago ati ojooro ni esi ti ajọ OGSIEC ọhun gbe jade ati pe o ti fihan daju pe iṣẹ ti APC ati Gomina Dapọ Abiọdun ran wọn, ni wọn jẹ, eyi ti ko si jẹ itẹwọgba ẹtọ ọmọniyan.


O ni ẹdun ọkan lo jẹ fawọn ni Imala, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, nibi ti wọn ti kede pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu wọn, lo wọlẹ nipo kansẹlọ nibẹ ṣugbon nigba ti yoo fi di ọgbọn iṣẹju sakoko naa, wọn ti yi esi ibo pada.

Alaga NNPP nipinlẹ Ogun tun sọ pe bẹẹ lọrọ ṣe ri kaakiri lawọn ibi kan ti ibo naa ti waye ṣugbọn tawọn ni ẹri to gbe gbogbo ẹ lẹsẹ. O ni pẹlu bawọn eeyan ko ṣe jade nibo ni wọn ẹgbẹ oṣelu APC ti ri awọn onka idibo ti wọn gbe jade.

Ọgiini tun wa sọ pe lati ibẹrẹ ti Ọṣibodu to jẹ alaga ajọ ọhun ti n gbe igbesẹ lawọn ti pariwo sita pe awọn ko nigbagbọ ninu ẹ. Pẹlu awọn nnkan to fara han ti wa jẹ kawọn araalu mọ pe ibo ẹtan lo waye naa.


O ni pẹlu bi gbogbo ẹ  ṣe wa ri bayii ile-ẹjọ ni yoo ba wọn yanju ti wọn yoo si gba ẹtọ wọn fun wọn pada. O wa ki awọn oludije ẹ ku oriire imurasilẹ lati gba ẹtọ wọn pada lọwọ awọn ti wọn pe ni jaguda, ti wọn fọsan ja wọn lole.

Bakan naa lo sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo to ran ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ lati ṣe magomago loun yoo ran lẹwọn, nitori awọn nnkan ti wọn ṣe lodi si ofin to ṣagbekalẹ ajọ eleto ibibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI