Bi ajoji ba wọ ipinlẹ Kwara lakooko ti a wa yii, yoo mọ pe inu idunnu ati ayọ nla ni gbogbo awọn araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa wa, ijọba lo si n mu inu wọn dun.
Awọn oṣiṣẹ ti ko din ni 463 la gbọ pe wọn ṣẹṣẹ jẹ anfaani iranwọ ẹyawo kan ti wọn pe ni Home Renovation Loan, eyi ti ajọ Federal Mortgage Bank of Nigeria ṣagbatẹru ẹ.
Nibẹ ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe ileri wi pe gbogbo anfaani to ba ti n yọ sita lawọn yoo maa mu lara rẹ lati fi dun awọn oṣiṣẹ patapata ninu.
A gbọ pe pupọ awọn oṣiṣẹ ni wọn ti fi orukọ silẹ tipẹ fun eto ẹyawo naa, ta a si gbọ pe ijọba ipinlẹ naa lo ṣokunfa bi owo naa ṣe tete jade nipa diduro fun gbogbo awọn to foukọsilẹ patapata.
Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq sọ pe "Eyi ni lati jẹ ki ẹ mọ pe ijọba to nifẹẹ yin lẹ yan sipo, ti emi naa si gbọdọ ri i daju pe mo ran yin lọwọ ni gbogbo ọna ti mo ba mọ patapata."
Iwuri nla ni Gomina yii sọ pe awọn oṣiṣẹ rẹ maa n jẹ foun ni gbogbo igba to ba ti n ri wọn, paapaa bi wọn ṣe n fi ara si iṣẹ, eyi lo si jẹ ko sọ pe oun ko ni i dawọ duro lati maa ṣe iranlọwọ to ba yẹ fun wọn.
No comments:
Post a Comment