Ẹmir tilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Sulu-Gambari ti yan Ọmọwe Muhammed Alimi Abdulrazaq gẹgẹ bi Mutawalle tuntun fun ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Ana, Ọjọbọ, Tọsidee ni Alaaji Sulu-Gambari kede agba amofin naa nilu Ilọrin.
Diẹ lara awọn nnkan to yẹ ki ẹ mọ nipa Mutawalle tuntun naa ree:
°Ọdun mejilelogoji ni Ọmọwe Muhammed Alimi Abdul-Razaq ti wa lẹnu iṣẹ agbẹjọro.
°Ilu Zaria ni wọn bi i si.
°Ọkan lara awọn to ni ileeṣẹ A. Abdul-Razaq (SAN) & Co. lo jẹ.
°Ileewe Capital to wa niluu Kaduna lo lọ, bẹẹ lo si tun lọ St Gregory’s College to wa niluu Ikoyi, ipinlẹ Eko.
°Fasiti Ahmadu Bello to wa ni Zaria lo kẹkọọ jade nipa iṣẹ Agbẹjọro.
°Oye LLM ati Ph.D lo gba ni fasiti Hull, to wa nilẹ Amẹrika.
°Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Chartered Institute of Arbitrators, Nigeria ni.
°O jẹ oloye ti wọn dibo yan ni Royal Institute of International Affairs, London.
°O wa ninu igbimọ First Bank Holdings
Yatọ si awọn wọnyi, o tun ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi i:
✓Commissioner, Legal Licensing and Enforcement fun ileeṣẹ Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC),
✓Chairman, National Iron Ore Mining Company, Itakpe,
✓Member, National Council on Privatisation.
✓O ti kopa nibi apejọ awọn adari ni ile ẹkọ iṣowo, Harvard Business School, ni fasiti Florida, fasiti Georgetown University ati Lagos Business School.
✓Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ amofin orilẹ-ede yii ati toke okun, International Bar Association, Nigerian Bar Association lo jẹ.
✓Oludasilẹ ati alaga Bridge House College, to wa ni Ikoyi, l'Ekoo ni.
✓AbdulRazaq i fẹ iyawo, bẹẹ ni Ọlọrun si tun jogun awọn ọmọ alalubarika fun un.
No comments:
Post a Comment