Lonii ni gbogbo awọn aṣofin ipinlẹ Kwara jade sita lati tako ọrọ minisita fun eto iroyin, aṣa ati irin ajo afẹ lorileede yii, Alaaji Lai Mohammed, to sọ pe oun gbe owo kalẹ fun ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ naa.
Lai Mohammed sọ pe oun ko gba owo lọwọ ẹnikẹni lori eto ipolongo idibo to waye nipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC. O ni owo apo ara oun loun na lori ipolongo idibo to gbe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq atawọn aṣofin ipinlẹ naa patapata wọle.
Nibi ipade tawọn aṣofin naa ṣe pẹlu awọn akọroyin nileeṣẹ awọn akọroyin ipinlẹ naa to wa nilu Ilọrin, ni wọn ti sọ pe irọ pọmbele ni Alaaji Lai Mohammed n paz ti ko si si otitọ kan ṣoṣo lẹnu ẹ.
Wọn lawọn ko fẹẹ sọrọ tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti Alaaji Lai Mohammed sọ pe oun na owo lori ipolongo ibo to gbe wọn wọle, eyi ti ko ri bẹẹ lawọn ṣe ni idi pataki lati jade.
Lara awọn ọmọ ile igbimọ to wa nibẹ ni: Ọnọrebu Abubakar Olawoyin Magaji; Ọnọrebu John Bello Olanrewaju; Ọnọrebu Musa Yusuf Atoyebi; Ọnọrebu Jimoh Ali Yusuf; Ọnọrebu Aliyu Wahab Opakunle; Ọnọrebu Rasaq Olatunde Owolabi; Ọnọrebu Danbaba Abdullahi Halidu; Ọnọrebu Ibrahim O. Ambali; Ọnọrebu Felix Omotayo Awodiji; Ọnọrebu Abdulgafar Olayemi Ayinla.
Awọn mi in ni: Ọnọrebu Muhammed Baba-Salihu; Ọnọrebu Ayokunle O. Awolola; Ọnọrebu Babatunde A. Paku; Ọnọrebu Gbenga A. Yusuf; Ọnọrebu Oyebode Olayiwola Ojo; Ọnọrebu Ahmed Saidu Baba; Ọnọrebu Gabriel G. Abolarin; Ọnọrebu Salahu Folabi Ganiyu; ati Ọnọrebu Adam Ahmed Rufai.
Yatọ si awọn wọnyi, Ọnọrebu Yakubu Danladi-Salihu to jẹ olori ile igbimọ aṣofin ati Ọnọrebu Raphael Olanrewaju Adetiba ti wọn dari ipade naa ko gbẹyin nibẹ.
Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe Lai Mohammed ko ṣe iranlọwọ kankan fun ẹnikẹni ninu wọn, ati pe ko bẹrẹ si i darukọ awọn to fun lowo lati polongo ibo lọdun 2019, ati iye to fun wọn.
Bẹẹ ni wọn sọ pe ọjọ ogbo lo n da Minisita naa laamu, eyi ti ko jẹ ko ranti ohunkohun mọ, to jẹ ko maa sọ isọkusọ kaakiri.
"Lati le jẹ kawọn eeyan mọ bi nnkan ṣe n lọ, a ni lati sọrọ, ka si fa komookun rẹ yọ. Oludije sipo Gomina nigba naa, iyẹn Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo gbe owo ipolongo idibo kalẹ fun wa. Nitori naa ki Lai Mohammed dẹkun lati maa pa irọ."
No comments:
Post a Comment