Ogun eṣu! Ọkan lara awọn ọlọpaa iyawo Gomina Fayẹmi l'Ekiti dero atimọle lori ẹsun ifipabanilopọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 14, 2021

Ogun eṣu! Ọkan lara awọn ọlọpaa iyawo Gomina Fayẹmi l'Ekiti dero atimọle lori ẹsun ifipabanilopọ


Ijọba ipinlẹ Ekiti ti fidi rẹ mulẹ wi pe ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto aabo to n tẹle iyawo Gomina Kayọde Fayẹmi, iyẹn Erelu Bisi Fayẹmi lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
 
Ọjọ karun-un, oṣu yii, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja la gbọ pe ọkunrin naa fipa ba obinrin kan laṣepọ karakara niluu Abuja.
 
Adajọ agba nipinlẹ naa, Ọlawale Fapounda ti fi ibinu sọrọ, o ni oṣiṣẹ eleto aabo ọhun yoo foju winna ofin, gẹgẹ bo ti tọ, ati bo ti yẹ, lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
 
A gbọ pe awọn ọlọpaa ilu Abuja ti bẹrẹ iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan ọlọpaa naa, ta a si gbọ pe ẹni ti ọlọpaa naa fipa ko ibasun fun ti wa nibi to ti n gba itọju, nipa ironu iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI