Ó ṣẹlẹ̀! Ẹ tún gbọ́ àṣírí ọ̀nà tuntun ti Igboho fẹ́ẹ́ gbà bọ́ mọ́ ìjọba Nàìjíríà lọ́wọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 21, 2021

Ó ṣẹlẹ̀! Ẹ tún gbọ́ àṣírí ọ̀nà tuntun ti Igboho fẹ́ẹ́ gbà bọ́ mọ́ ìjọba Nàìjíríà lọ́wọ́

 
Iroyin to tun tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti fi ye wa pe Oloye Sunday Adeyẹmọ, tọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti kọ iwe ẹbẹ si ijọba ilẹ Biritiko (Britain) fun iranlọwọ ibi ifipamọ (Asylum) lati ma jẹ ki orilẹ-ede Naijiria gbe e.
 
Eyi waye lakooko ti ijọba Naijiria n gbe igbesẹ lati gba Sunday Igboho kuro lọwọ ijọba ilẹ Benin, ki wọn le gbe e pada sile lati le foju rẹ ba ile ẹjọ.
 
Bẹ o ba gbagbe, alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ijẹta lọwọ awọn ọlọpaa agbaye, Interpol tẹ Igboho ni papakọ ofurufu to wa lorilẹ-ede Benin, lakooko to fẹ maa lọ si orilẹ-ede Germany, nibi to tun ti niwe igbelu pẹlu iyawo rẹ, Rọpo.
 
Ọkan lara awọn agbẹjọro Oloye Igboho niluu Texas, Ebenezer Ọlanrewaju la gbọ pe o fidi iroyin yii mulẹ wi pe awọn ti kọ iwe iranwọ fun ibi ifipamọ, eyi ti ko ni jẹ ki ijọba Naijiria fiya jẹ Igboho lọna ti ko tọ.
 
O tun sọ siwaju pe ijọba Benin ko ni idi pataki ti wọn le fi f'Igboho silẹ fun ijọba Naijiria, nitori pe ko ni ẹṣẹ kankan lọdọ wọn.
 
"A ti wa lori ọrọ naa, a ti jẹ ki ijọba Biritiko mọ ohun ajalu ti yoo ṣẹlẹ si Igboho ti wọn ba fi le gbe e pada lọ si Naijiria, ati pe, inu ewu nla ni ẹmi rẹ wa."
 
O tẹsiwaju pe,
"Nigba ijọba Biritiko ba fi le fi ọwọ si iwe ẹbẹ tawọn kọ naa, yoo ṣe ijọba Benin ni kayeefi, ti wọn yoo si jẹ ko tẹsiwaju lati maa lọ silẹ Europe to n lọ. Awọn alatilẹyin ominira Yoruba ti n fẹhonu han lati jẹ ki ijọba Naijiria yọwọ kuro lori ọrọ naa"

2 comments:

  1. Ejowo nitori Ọlọrun ọba o, eba wa sanu oloye Sunday Igboho osha o, ija mekunu lo ngbe o.

    ReplyDelete
  2. E bawa fi chief Sunday igboho sile o,Tori leyin Olorun oba Sunday igboho loku toleja fun awa mekunu o,ti ijoba ba ko tiwonsope won o ni je ki Sunday Simi ibanuje,ofo, wahala lomaje to gbogbo awon towa Lori ijoba o,konirorun fun gbogbo Iran won lase Edumare 🙏

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI