Ó parí o, Baálẹ̀ ìlú dèrò ẹ̀wọ̀n lórí ẹsùn jìbìtì ilẹ̀ n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 29, 2021

Ó parí o, Baálẹ̀ ìlú dèrò ẹ̀wọ̀n lórí ẹsùn jìbìtì ilẹ̀ n'Ibadan


Ọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, (EFCC), ẹka tiluu Ibadan ti tẹ gbajumọ baalẹ ilu Onidundu to wa nijọba ibilẹ Akinyẹle, ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, Oloye Ọlagoke Samson Amọo, lori ẹsun jibiti ilẹ ti wọn fi kan an.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ilẹ ni Oloye Ọlagoke Amọo fi n lu jibiti kaakiri ilu Onidundun, nibi to ti jẹ Baalẹ.
 
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ EFCC gbe soju opo wọn laipẹ yii ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti foju Oloye Amọo, ẹni ọdun mejilelọgọrin ba ile-ẹjọ giga tipinlẹ Ọyọ to wa niluu Ibadan, niwaju Onidajọ Iyabọ Yẹrima.
 
 
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu jibiti la gbọ pe wọn fi kan Baalẹ naa nile-ẹjọ, gẹgẹ EFCC ṣe ṣalaye.
 
Wọn ni ẹnikan lo mu ẹsun Oloye Amọo wa fawọn wi pe baba naa ta ilẹ eeka mẹrin foun ni miliọnu mẹrin naira, ṣugbọn to sọ pe asiko toun fẹẹ bẹrẹ iṣẹ lori ilẹ ọhun lawọn kan de, ti wọn si lawọn lẹni to ni ilẹ naa.

Onidajọ Yẹrima ti wa a paṣẹ pe ki Oloye Amọo ṣi wa lọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ mi in yoo waye.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI