Adura tawọn eeyan maa n gba pe ki Ọlọrun ma jẹ ka kagbako, ati pe ki Ọlọrun ma jẹ ka ku lọjọ ti ire ayọ wa ba wọle de ko gba rara fun baba onile kan l'Ekoo lọjọ ọdun Ileya ti wọn ṣe lanaa, Tusidee.
Ojule kẹtadinlaadọrin, agbegbe Tapa, Oke-Ojo, Iṣawọ niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko la gbọ pe ile naa wa, ti wọn sọ pe wọn ṣẹṣẹ n kọ lọwọ. Daniẹli Ọbasi ni wọn pe orukọ baba onile naa, koda, a gbọ pe pasitọ ṣọọṣi kan ni pẹlu.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, wọn ni ọjọ Aje, Mọnde, ijẹta lawọn agbaṣẹṣe ti ṣiṣẹ gbẹyin ninu ile naa, ti wọn si kede isinmi wi pe iṣẹ ko ni i waye lanaa.
A gbọ pe ṣe ni Daniẹli lọ lati lọ wo ibi ti awọn agbaṣẹṣe naa ba iṣẹ de, ko si le mọ awọn nnkan to ku ti yoo ra fun iṣẹ ile ọhun lati tete pari.
Ibi ti wọn ni Daniẹli ti n lọ kaakiri ni wọn sọ pe ile naa ti wo lulẹ lojiji, iyẹn ni nnkan bi aago meji aabọ ọsan, lakooko ti pọpọṣinṣin ọdun Ileya n lọ lọwọ.
Awọn to ri nnkan to ṣẹlẹ yii, ni wọn sare lọ sibẹ lati doola ẹmi Daniẹli, koda, ti wọn lawọn kan tun ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ ileese to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, National Emergency Management Agency, NEMA, nipinlẹ Eko fun iranlọwọ.
Nigba ti wọn si maa fi ri Daniẹli yọ kuro labẹ okuta ile to wo lu yii, ẹpa ko boro mọ rara.
Adari ajọ NEMA nipinlẹ Eko, Ibrahim Farinloye nigba to n sọrọ sọ pe iṣẹlẹ naa ṣe laanu, to si jẹ ko ye wa pe ai jẹ ki simẹnti ti wọn fi tẹ oke ile naa, ati awọn opo to di ile naa mu gbẹ daadaa ki wọn too tẹsiwaju iṣẹ lo fa a ki ile naa wo lulẹ lojiji.
Farinloye lawọn ọlọpaa ẹkun Isawọ lo gbe oku Daniẹli lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko.
Diẹ ree lara awọn fọto iṣẹlẹ naa:
No comments:
Post a Comment