Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a pari iroyin yii ni a ko ti i le fidi iku to pa gbajugba agba oṣerebinrin nni, Rachel Tabuno Oniga mulẹ, ṣugbọn ta a gbọ pe alẹ ana, ọjọ Ẹti, Furaidee lo jade laye.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni agbara oṣerebinrin to kọ ọkọ rẹ silẹ lọdun mọkandinlogun sẹyin.
A gbọ pe lati ibere ọsẹ yii ni oṣerebinrin naa fi wa niluu Mowe, ipinlẹ Ogun nibi to ti lọọ ṣiṣẹ ere fiimu kan ti wọn n popọ lọwọ.
Gbogbo awọn ollufẹ iṣẹ tiata, paapaa awọn oṣere tiata ni wọn ti n banujẹ gidi lori iku obinrin naa.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe arun korona, COVID-19 lo ṣeku pa obinrin naa.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 0957 ni wọn bi Rachel Oniga. Ọmọ ijọba ibilẹ Ethiope nipinlẹ Delta ni.
Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ
No comments:
Post a Comment