Ọrọ buruku toun tẹrin pẹlu bi wọn ṣe sọ pe gendekunrin ti ẹ n wo yii ṣe ji ọkan lara awọn ṣọja orile-ede yii gbe nipinlẹ Ogun, to si gba aṣọ lọrun rẹ.
AWIKONKO gbọ pe opin ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii ni gendekunrin naa, Wasiu Oloyede ji ṣọja ọhun gbe, to si gba aṣọ ati dukia lọwọ rẹ.
Wọn ni Waliu ati awọn ọrẹ rẹ meji tawọn ti na papa bora ni wọn jọ ji ṣọja naa gbe ni nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ti wọn si gbe e lọ si buba wọn ni Alagbado niluu Eko, nibẹ ni wọn ti gba aṣọ lọrun rẹ.
Yatọ si aṣọ ti wọn gba yii, wọn tun gba kaadi idanimọ rẹ, kaadi ATM ẹ, to fi mọ foonu ẹ.
A gbọ pe lẹyin ti wọn gba gbogbo nnkan naa tan, ṣe ni Waliu bẹrẹ si i fi aṣọ naa lọ lu jibiti. Wọn ni ṣe lo tun lọ fi aṣọ naa koju awọn Fijilante to wa lagbegbe Odo Pako ni Ọta, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun.
Lara awọn to ri bi nnkan ṣe n lọ la gbọ pe wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa.
Nigba tawọn ọlọpaa maa debẹ ni wọn ṣakiyesi bpe ayederu ṣọja ni Waliu, eyi lo jẹ ki wọn gbe e lọ teṣan wọn.
Funra rẹ lo pada jẹwọ bo ṣe ri aṣọ naa jigbe, to si bẹbẹ fun idariji.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun ti pàṣẹ pe ki iwadii tubọ bẹrẹ lori ẹ, ki wọn si ri i daju pe ọwọ tẹ awọn yooku rẹ lati foju wọn ba ile ẹjọ.
No comments:
Post a Comment