Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe ipolongo idibo ijọba ibilẹ to n lọ lọwọ ko ni lee waye mọ titi ayẹyẹ ati pọpọṣinṣin ọdun Ileya yoo fi pari.
Igbakeji gomina ipinlẹ naa, Onimọ-Ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, ẹni to tun jẹ alaga ipolongo idibo ijọba ibilẹ lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita lanaa, Abamẹta, Satide.
O ni ki awọn eeyan le farabalẹ gbadun ọdun Ileya yii, ati isinmi daadaa, ipolongo to yẹ ko waye lọjọ Aje, Mọnde ọla ko ni lee waye mọ, ati pe Ọjọbọ, Tọsidee, ni yoo pada waye.
Salakọ-Oyedele wa a dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn ti jọ n kaakiri lati ṣe ipolongo naa, paapaa awọn Ọba alaye, awọn agbaagba ẹgbẹ APC, awọn ọlọja, oniṣowo, ajọ, ileeṣẹ, ẹgbẹ akẹkọọ, eleto aabo atawọn mi in fun atilẹyin wọn.
No comments:
Post a Comment