Nítorí ẹ̀sun jìbìtì, wọ́n gbé Yahaya Bello lọ sọ́dọ̀ àjọ EFCC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 23, 2021

Nítorí ẹ̀sun jìbìtì, wọ́n gbé Yahaya Bello lọ sọ́dọ̀ àjọ EFCC


Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Anti-Corruption Network, ti fi ẹsun iwa jibiti kan gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lọdọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial crime commission, EFCC.
 
Wọn lawọn fẹ ki ajọ EFCC ṣe iwadi Gomina naa daadaa, nitori pe iṣakoso rẹ lẹbọ-lẹru.
 
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii ni ẹgbẹ naa kọwe ẹsun nipa Yahaya Bello ranṣẹ si ajọ EFCC, ati awọn kan, wi pe wọn lọwọ si gbigbe owo nla kan salọ laaarin ọdun 2016 si ọdun 2019.
 
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa tun gbe jade lanaa, wọn fẹsun kan ajọ EFCC wi pe wọn ko ṣe ohun to yẹ lati ri i wi pe wọn mu gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati fi wọn jofin.
 
Bẹẹ ni wọn tun lawọn yoo ti ẹsẹ ofin bọ ọrọ, iyẹn bi ajọ EFCC ba kọ lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, laaarin asiko ti wọn fun wọn da.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI