Mọ́tọ̀ tẹ alaaganna pa l'Abẹ́òkúta, làwọn tọ́rọ̀ kan bá kọ̀ láti gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 25, 2021

Mọ́tọ̀ tẹ alaaganna pa l'Abẹ́òkúta, làwọn tọ́rọ̀ kan bá kọ̀ láti gbe


Oku ti ẹ n wo yii ni oku alaaganna kan ti mọto gba danu siwaju ile ẹkọ girama tiluu Ẹgba, iyẹn Egba Comprehensive High School to wa ni Aṣero, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. 
 
Awọn oṣiṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, TRACE la gbọ pe wọn gbe oku alaaganna kuro loju titi lati le jẹ ki awọn mọto maa lọ bo ṣe yẹ.
 
Latigba naa ni wọn sọ pe wọn ti ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, Emergency Management Agency lati wa a gbe oku naa, ṣugbọnt ti wọn ni ko ti i sẹni to yọju latigba naa, titi ta a fi pari iroyin yii laago mẹwaa ku iṣẹju mẹwaa {9:50pm}.
 



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI