Olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti pariwo sita wi pe oun ko lọ siluu Eko mọ lati lọ ṣe iwọde ipolongo ifẹhonu han lati da orileede Oduduwa silẹ, iyẹn Yoruba Nation.
Ọjọ Abamẹta, Satide to n bọ yii ni Igboho ti ni i lọkan lati ṣe iwọde naa. Kaakiri awọn ilẹ Yoruba lo si ti lọ ṣe awọn iwọde wọnyi.
Nigba to n ba awọn akọroyin BBC aladamọ-ede gẹẹsi {Pidgin} sọrọ lonii ni Igboho sọ pe awọn ti sun iwọde naa siwaju, ṣugbọn ti ko mẹnuba ọjọ kan pato ti iwọde naa yoo waye.
Ko pẹ ti iroyin jade sita awọn agbebọn yawọ ile Sunday Igboho to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti wọn ti pa eeyan meji, ti wọn si tun ji iyawo rẹ gbe salọ ni Igboho sọrọ naa jade.
O sọ pe nitori ọrọ eto aabo loun ṣe fagile iwọde naa fungba diẹ.
No comments:
Post a Comment