Lẹyin to lọ bawọn kẹdun iku Emir Haliru, wọn lawọn araalu yẹyẹ Saraki ni Patigi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 19, 2021

Lẹyin to lọ bawọn kẹdun iku Emir Haliru, wọn lawọn araalu yẹyẹ Saraki ni Patigi


Aarẹ ile igbimọ aṣofin orile-ede yii tẹlẹri, Sẹnetọ Bukọla Saraki ko le gbagbe yẹyẹ ti wọn lawọn ara agbegbe Patigi, nipinlẹ Kwara fi ṣe lori ọna to wọ agbegbe ọhun lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii.
 
Ibi ti wọn ni Saraki ti lọ bawọn kẹdun iku Emir ilu Patigi, Alaaji Sa'adu Kawu Haliru la gbọ pe awọn eeyan ti yẹyẹ, ti wọn si bẹrẹ si i sọ oriṣiriṣi ọrọ kungbakugbe si i.

Ninu lẹta ti aarẹ ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Patigi Political Front, PPF, nijọba ibilẹ Patigi, Alaaji Yahaya Mohammed gbe jade lẹyin abẹwo Saraki siluu naa ni wọn ti sọ pe awọn ko le gbagbe iya to fi jẹ wọn lasiko to wa nijọba, paapaa ipo agbara to ti le ṣe awọn nnkan to n fẹ.
 
Wọn loo lọwọ bi ọna naa ko ṣe di ṣiṣẹ lakooko ijọba rẹ, eyi to mu ki eto ọrọ aje wọn lọ silẹ patapata. Wọn ni mọto ko le gba ọna yii kọja lai bajẹ, ati pe asiko ti ojo ba ti rọ, awọn mọto ki i raaye kọja rara.
 
Ẹgbẹ yii sọ pe Saraki pẹlu awọn to gbe akanṣe iṣẹ ọna naa fawọn agbaṣẹṣe, ti ko si bojuto bawọn agbaṣẹṣe naa ko ṣe pari rẹ lasiko to yẹ, to jẹ pe ọwọ yọbọkẹ ni wọn fi mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI