Ìjọba ilẹ olominira Benin ti sọ pe awọn ko ni i wo gbogbo idunkooko ti ijọba Naijiria n dun mọ awọn lori ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, eyi ti yoo mu kawọn fọwọ pa ida ofin wọn loju.
Fun idi eyi, wọn lawọn ko ti i le fi Sunday Igboho silẹ fun ẹnikẹni.
Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii lọwọ awọn ọlọpaa agbaye, Interpol tẹ Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Cadjèhoun to niluu Cotonou, orilẹ-ede olominira Benin.
Latigba naa ni ijọba Naijiria ti n gbiyanju lati gba Igboho kuro lọwọ wọn, lori ẹsun ti wọn ti fi kan an ṣaaju wi pe o n ko ibọn pamọ sinu ile ẹ.
Ijọba Benin sọ pe ọna ti ijọba Naijiria fẹẹ gba gbe Sunday Igboho kuro lọdọ awọn ko ba ilana ati ofin ilẹ wọn mu, ati pe gbogbo agbaye lo n wo wọn.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto aabo ilẹ Benin bẹbẹ lati fi orukọ rẹ pamọ sọ pe:
"Ijọba Naijiria gbiyanju lati gbe Igboho kuro nibi, ṣugbọn ijọba wa sọ pe awọn gbọdọ tẹle ilana ofin, wi pe gbogbo agbaye lo n wo wa."
Ọkan lara awọn agbẹjọro fun Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi to bawọn akọroyin sọrọ sọ pe ijọba Benin ti fi ara wọn han daju wi pe wọn maa n bọwọ fun ilana ati ofin.
O lawọn ti n ba ijọba Benin sọrọ lori ọrọ Igboho.
No comments:
Post a Comment