Kafayat, ọ̀dájú abiyamọ fi àfọ́kù ìgò gún ọmọ rẹ̀ pa l'Ogijo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 31, 2021

Kafayat, ọ̀dájú abiyamọ fi àfọ́kù ìgò gún ọmọ rẹ̀ pa l'Ogijo


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ iyaale ile, ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Kafayat Lawal to gun ọmọ rẹ, Ayọmide Adekọya, ọmọ ọdun mẹtadinlogun pa.

Yatọ si Ayọmide ti Kafayat fi afọku igo gun pa ni kete ti ọdun Ileya to kọja yii pari, o tun fi afọku igo kan naa gun akọbi ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mọkandinlogun, Blessing Adekọya lọwọ, to si jẹ pe ori lo kọ ohun yọ lọwọ iku ojiji.
 
Ẹsun ti Kafayat fi kan awọn ọmọ rẹ mejeeji yii ni pe wọn jade lọjọ ọdun Ileya, wọn ko si pada wọle. O ni ọjọ keji ni wọn ṣẹṣẹ pada dele. Ọjọ naa la gbọ pe Kafayat ti fẹẹ lu awọn ọmọ rẹ, ṣugbọn ti a gbọ pe awọn araale ni wọn ko jẹ ko ri wọn lu.
 
Awọn ọmọ yii la tun gbọ pe wọn jade lọ lọjọ keji ọjọ ti wọn pada de yii, ti wọn ko si tun pada lọ sile lati lọ sun. A tiẹ gbọ pe ile ọkunrin ni wọn lọ n sun, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ.
 
Bi wọn ṣe pada de ni Kafayat ti n beere ibi ti wọn ti n bọ, ṣugbọn ti ọrọ awọn mejeeji ko ba ti ara wọn, eyi lo mu ki obinrin yii ti wọn mọnu ile, to si yọ igo afọku si wọn.
 
Ṣe lo gun wọn kọja sisọ, ti igo naa si pada ba Ayọmide lọkan. Ariwo wọn yii lo jẹ ki awọn araale sare debẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ri awọn ọmọ mejeeji ninu agbara ẹjẹ.
 
Wọn ko fi ọrọ yii falẹ rara ti wọn fi sare gbe wọn lọ si ọsibitu fun itọju, to si pada ṣeni laanu wi pe Ayọmide jade laye.
 
Awọn ara adugbo lo lọ fa Kafayat le awọn ọlọpaa lọwọ, ti wọn si fọrọ wa a lẹnu wọ. Nigba to n sọrọ, Kafayat sọ pe iṣẹ eṣu ni.
 
Edward Awolọwọ Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju Kafayat ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI