Ile ẹjọ giga kan to wa niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee ti ju oṣiṣẹ banki tẹlẹ kan, Ebenezer Adeolu Alonge ati iyawo rẹ, Isakunle Ọlamide Oyinlọla sẹwọn ọgọ ọdun gbako, pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ki i ṣe awọn mejeeji yii nikan ni ile ẹjọ naa ju sẹwọn ọgọta ọdun, iya iyawo Adeolu, iyẹn Arabinbin Isakunle Eunice Moradekẹ pẹlu awọn ti yoo fi ẹwọn yii gbara, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Onidajọ Adekanye Ogunmoye ti ile ẹjọ giga naa nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹsun mejila ọtọọtọ ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta lo ti sọ pe wọn jẹbi awọn ẹsun naa nipasẹ awọn ẹri aridaju toun ri gba.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lo gbe awọn mẹtẹẹta ọhun lọ sile ẹjọ.
Wọn ni ẹsun ti wọn fi kan wọn ni i ṣe pẹlu ole jija, eyi to tako iwe ofin ọdaran orilẹ-ede yii, tọdun 2012, to si ni ijiya ninu labẹ ofin.
Onidajọ Ogunmoye, ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn ẹri toun ri gba lati ọdọ awọn agbẹjọro ajọ EFCC ti Abdulrasheed Lanre Suleiman lewaju wọn fi han daju pe loootọ ni wọn lu jibiti naa, ati pe wọn jẹbi kọja sisọ.
EFCC, la gbọ pe wọn pe ẹlẹri meji ọtọọtọ wa siwaju ile ẹjọ lati tako wọn, bẹẹ ni wọn tun ko oriṣiriṣi awọn ẹri mi in silẹ fun adajọ, lati fi han pe awọn ko purọ mọ wọn.
Lẹyin rẹ ni ile ẹjọ sọ pe ki awọn mẹtẹẹta lọọ fi ẹwọn ọdun marun-marun-un gbara lori ẹsun kọọkan, eyi ti akojọpọ rẹ jẹ ọgọta ọdun.
AWIKONKO gbọ pe banki ti Adeolu ti n ṣiṣẹ tẹlẹ lo mu ẹsun rẹ lọ ba ajọ EFCC, wi pe o lọwọ si iwa jibiti ati ole jija lọdọ awọn, ati pe ki wọn ba wọn ṣe iwadii rẹ daadaa, iyẹn ninu oṣu keji, ọdun 2018.
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 2017 ni wọn sọ pe ọkan lara awọn onibaara banki yii lo wa a fi ẹjọ wi pe wọn yọ owo oun, ẹgbẹrun mejilelọgtọta ati irinwo naira {N62,400.00} ninu apo owo oun.
Wọn ni obinrin naa sọ pe oun san owo naa sinu apo owo oun, ṣugbọn toun ko ri i nibẹ. Ẹni naa lo sọ pe Adeolu lo gba owo yii lọwọ oun lọjọ naa.
Ninu iwadii ni wọn ti pada ri i pe inu apo owo iyawo Adeolu ni wọn ti pada ri owo yii. Siwaju si i, nigba ti aṣiri tun maa tu, wọn tun ri i pe oriṣiriṣi owo lo ti wọ inu apo owo obinrin naa, ti apapọ owo naa si jẹ miliọnu mọkanlelogun naira.
Bakan naa niwadii tun tu aṣiri wi pe iya iyawo Adeolu naa wa lara awọn ti wọn jọ n gba owo yii.
Yatọ si ẹwọn ọgọta ọdun ti ile ẹjọ ju wọn si, ile ẹjọ tun gbẹsẹ le ile ti Adeolu kọ, lati fi da awọn owo ti ti jale rẹ pada fun banki ọhun.
No comments:
Post a Comment