Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ko ma jẹ pe ile-ẹjọ ni ipade gbogboogbo to fẹẹ bẹrẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lorilẹ-ede yii lọjọ Abamẹta, Satide to n bọ yoo pada gbẹyin si.
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe ko si nnkan to le da ipade gbogboogbo naa duro, bo ti le wu ki wahala pọ to ninu ẹgbẹ wọn, nitori pe awọn yoo pada yọnju ẹ laaarin ara wọn.
Idajọ ile-ẹjọ agba lori eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo ti n fi aridaju han wi pe wahala n bọ ninu ẹgbẹ APC kaakiri Naijiria, pẹlu bi ile-ẹjọ agba ṣe sọ pe ọna ti ko ba ofin mu ni wọn fi yan Gomina Mai Mala Buni gẹgẹ bi alaga.
No comments:
Post a Comment