Iléyá! Wọ́n yọ ọ̀bẹ si Ààrẹ ilẹ̀ Mali ní Yídì, wọ́n làsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọdele ló wá sí ìmúṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 20, 2021

Iléyá! Wọ́n yọ ọ̀bẹ si Ààrẹ ilẹ̀ Mali ní Yídì, wọ́n làsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ayọdele ló wá sí ìmúṣẹ


Ọkan lara awọn asọtẹlẹ Wolii Babatunde Elijah Ayọdele, alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual kaakiri agbaye nipa orilẹ-ede Mali ati Pẹru lo tun ti wa si imuṣẹ bayii o.

Ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin ni Wolii Ayọdele gbe iwe asọtẹlẹ ọlọọdun rẹ, to pe ni 'Warnings To The Nations' jade, nibi to ti sọ awọn nnkan ti yoo ṣẹlẹ lawọn orilẹ-ede kaakiri.
 
Gbogbo igba si ni Wolii Ayọdele maa n sọ wi pe awọn asọtẹlẹ oun ki i ṣe fun orilẹ-ede Naijiria nikan, bi ko ṣe kaakiri agbaye, iyẹn awọn ibi ti Ọlọrun ba ran oun si.
 
Wolii Ayọdele sọ pe rogbodiyan ati igbogun ti yoo dide lodi si Aarẹ fidihẹ lorilẹ-ede Mali, Asimi Goita, ti awọn araalu yoo si kọju ija sira wọn.
 
Bẹẹ gẹlẹ lo ri ni nnkan bi wakati meloo kan sẹyin, ti a gbọ pe awọn eeyan yọ ọbẹ si Aarẹ fidihẹ naa ni mọṣalaṣi, nibi to ti lọọ gbadura ọdun Ileya.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn lawọn oṣiṣẹ aabo rẹ ni wọn sare gbe e wọ mọto, ti wọn si gbe e salọ kuro ni Yidi naa.

Ninu asọtẹlẹ Wolii, o ni:
“Inu idaamu ni Aarẹ Mali, iyẹn aarẹ fidihẹ wọn yoo ti maa ṣiṣẹ, ki wọn ma ba a lẹ jẹ ki iṣakoso pẹ lori ipo naa. O maa gbiyanju lati ṣe daadaa, ṣugbọn ẹ jẹ ka gbadura lodi si wahala ati rogbodiyan, ati ikọlu.

"Aarẹ gbọdọ ṣọ irin rẹ gidi nitori awọn eeyan yoo fẹẹ gbẹsan lati da ijọba rẹ ru.  Bawọn ologun ṣe mu ọrọ eto aabo yoo pe fun iranlọwọ agbaye."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI