Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun, ìyẹn Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps ti a tun mọ si So-Safe Corps fi sọ pe ki gbogbo awọn araalu patapata lọ fi ọkan wọn balẹ lori eto aabo lasiko ayẹyẹ ati pọpọṣinṣin ọdun Ileya to wọle de yii.
Ninu atẹjade ti Mọruf Yusuf to jẹ alukoro ileeṣẹ naa fi ranṣẹ si AWIKONKO laipẹ yii lo ti sọ pe gbogbo eto lo ti to patapata, ati pe ki awọn araalu lọ fọkàn balẹ lori awọn ti yoo fẹ lo anfaani ọdun Ileya lati ṣiṣẹ ibi.
Yusuf sọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti pàṣẹ fun gbogbo awọn adari lawọn ẹkún wọn kaakiri ipinlẹ naa lati mura giri lakooko ọdun Ileya.
O ni ki wọn ri i daju pe awọn araalu ṣe ọdun yii ninu ibalẹ ọkan ati alaafia lai ni ibẹru awọn oniṣẹ ibi lọkan wọn.
Bakan naa lo gba awọn araalu lamọran wi pe ki wọn pe awọn nọmba wọnyii, 09069392064, 08035479930, 08028286064, bi wọn ba kofiri iwa ọ̀daràn lagbegbe wọn.
No comments:
Post a Comment