Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin musulumi patapata kaakiri ipinlẹ naa, paapaa lorilẹ-ede Naijiria yọ ayọ pọpọṣinṣin ọdun Ileya to n lọ lọwọ.
O gbawọn eeyan lamọran lati wo awokọṣe awọn iwa ati ẹkọ ti Wolii Ibrahim fi kọ wọn, ki wọn si maa fi ba gbogbo eeyan ṣe patapata.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina Dapọ Abiọdun, Kunle Ṣomọrin fi sita laarọ oni, Tusidee lo tun ti sọ peki wọn lo anfaani ọdun yii lati fi gba alaafia, iṣọkan ati ifẹ laaye laaarin ara wọn.
O ni bo tilẹ jẹ pe orilẹ-ede yii n koju awọn iṣoro loriṣiriṣi, sibẹ, o ni ṣe lo yẹ kawọn ọmọ Naijiria lo anfaani asiko yii lati fi gbadura, ki wọn si sunmọ Ọlọrun lati le tan iṣoro ti ilẹ yii n doju kọ.
No comments:
Post a Comment