Ilẹ̀ Amẹ́ríkà tú àṣírí bí gbajúmọ̀ ọlọ́pàá ṣe gba òbítíbitì owó lọ́wọ́ Hushpuppi, gbajúmọ̀ onínakùná àgbáyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 30, 2021

demo-image

Ilẹ̀ Amẹ́ríkà tú àṣírí bí gbajúmọ̀ ọlọ́pàá ṣe gba òbítíbitì owó lọ́wọ́ Hushpuppi, gbajúmọ̀ onínakùná àgbáyé

IMG_ORG_1627625372748

Ileeṣẹ eto idajọ nilẹ Amẹrika {United States Department of Justice} l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii ti tu aṣiri bi ọkan lara awọn gbajumọ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Abba Alhaji Kyari, ẹni to tun jẹ igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ṣe gba obitibiti owo ẹyin lọwọ Ramon Abbas, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppi.

Ninu iwe nla kan ti wọn gbe jade, nibẹ ni wọn ti ṣalaye gbogbo awọn mẹfa to lọwọ ninu jibiti ti wọn lu ẹnika.
 
Bakan naa ni wọn tun tu aṣiri gbogbo ajọsọ ati ifọrọwerọ to wa laaarin Kyari ati Hushpuppi, nibi ti wọn lo ti n sọ pe ki wọn ba oun ti Kelly Vincent Chibuzor, ẹni ogoji ọdun mọle, ṣugbọn to tun pada ba a bẹbẹ.
 
Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun {N300,000} naira la gbọ pe Kyari gba lọwọ Hushpuppi, ko to ṣiṣẹ naa.


Justice-.-gov

Ṣugbọn nigba tako ẹsun ti wọn fi kan an, Abba Kyari l'Ọjọbọ, Tọsidee ana sọ pe irọ nla ni wọn pa mọ oun, nitori pe ko sẹni to beere owo lọwọ ẹnikẹni lati mu ẹnikan.
 
O ni lati le doola ẹmi ati dukia araalu ni ọlọpaa wa fun un, paapaa lati fi ọwọ ofin mu awọn ti wọn ba n dunkooko mọ ẹmi eeyan.

Kyari ṣalaye pe Hushpuppi lo fi ọrọ rẹ to awọn leti wi pe ẹnikan wa ni Naijiria to n dunkooko mọ oun, ati pe ẹni naa fẹẹ pa gbogbo mọlẹbi oun run. O ni Dubai ni Hushpuppi n gbe ko to fi ẹsun naa kan ẹni yii, to si tun fi nọmba ẹni naa ranṣẹ sawọn, pẹlu bo ṣe n bẹ ileeṣẹ ọlọpaa lat tete gbe igbesẹ.

O lawọn pada fi ẹni naa silẹ nigba ti iwadii fi han wi pe ọrẹ timọtimọ lawọn mejeeji, ati pe ẹni naa ati Hushpuppi jọ ṣe iṣẹ kan ti o nii ṣe pẹlu owo, owo yii lo sọ pe o da wahala silẹ laaarin wọn. O loun ko gba tabi beere owo lọwọ Hushpuppi.
 
O nigba ti ọrọ owo jọ da awọn papọ nigba ti Hushpuppi beere ẹni to n ba oun ran awọn aṣọ ati fila ibilẹ oun, ati pe lẹyin toun fi ẹrọ ibanisọrọ ẹni naa ranṣẹ si i lo fi owo naa ranṣẹ si i lati ba a fi ran aṣọ oriṣi marun-un ọtọọtọ.
 
O tẹsiwaju pe lẹyin ti ẹni naa pari awọn aṣọ ọhun, lo ko o wa si ọfiisi oun, ti ẹni kan si lọ ko o fun Hushpuppi nibi to wa. Bẹẹ lo sọ pe ki ẹnikẹni to ba fẹẹ mọ siwaju si i pe Vincent lati beere lọwọ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *