Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, Igboho, olori ajijangbara ilẹ Yoruba ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti ijọba ilẹ Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari fi kan oun wi pe oun n ṣe fayawọ ibọn ati awọn nnkan ija oloro wọnu ilu.
Bẹẹ lo sọ pe ko si otitọ kankan ninu ohun ti ijọba Naijiria sọ nipa oun wi pe oun n da ogun ati ija ẹlẹyamẹya silẹ laaarin ilu, bi ko ṣe pe oun n gbeja awọn mọlẹbi oun ti awọn Fulani darandaran n pa nipakupa.
Aṣiwaju awọn agbẹjọro rẹ, Ibrahim Salami lo sọ eyi di mimọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lanaa, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Salami ni, ohun ti Igboho sọ fun adajọ ni pe ijọba Naijiria n wa oun nitori pe oun dide lati kọju ija sawọn Fulani darandaran ti wọn n oawọn eeyan oun.
O ni ẹsun tuntun ti ijọba Benin fi kan Igboho ni pe o wọ orilẹ-ede Benin lọna ti ko ba ofin mu, bẹẹ lo tun lẹdi apo pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ aṣọbode lọna jibiti, ati igbiyanju lati da awuyewuye silẹ.
"Igboho ṣalaye irọ ni gbogbo nnkan ti wọn sọ nipa oun.
"O ṣalaye pe oun ko se nnkan to lodi si ofin ni Naijiria. O ni ijoba Naijiria ko fi ẹsun kan oun nile ẹjọ, tabi pe wọn ju oun sẹwọn lori ẹsun kankan, wọn ko fi ọwọ ofin mu oun lori ẹsun kankan, bẹẹ ni awọn ọlọpaa ko ranṣẹ pe oun.
"O ni ijọba Naijiria n le oun nitori pe oun n ka fun awọn ọmọ Yoruba lati gba wọn silẹ lọwọ awọn Fulani darandaran. O loun sa kuro ni Naijiria nitori pe ijọba n lepa ẹmi oun.
"Nigba ti wọn beere lọwọ ẹ nipa igba to wọ Benin, ati bawo lo ṣe wọle. Igboho sọ pe ọjọ Aiku, Sannde loun kuro ni Naijiria, toun si wọ Benin lọjọ Aje, Mọnde, ati pe alẹ ọjọ Mọnde naa loun fẹẹ maa lọ si Germany, ko to di pe wọn mu oun.
"Adajọ beere lọwọ ẹ pe nibo lo gbe, ta lẹni to wa a, bawo lawọn agbofinro ko ṣe ri i. O dahun ibeere naa
"Oun to ya ni lẹnu ni pe adajọ sọ pe ki i ṣe nitori pe o ṣe ni wọn ṣe mu Igboho, bi ko ṣe pe o tapa si ofin Benin, ti awọn si gbọdọ ṣe iwadii ẹ."
Olorun ase afayo won
ReplyDelete